Leviticus 27:30-33

30 a“ ‘Gbogbo ìdámẹ́wàá ilẹ̀ náà yálà tí èso ilẹ̀ ni, tàbí tí èso igi, ti Olúwa ni. Mímọ́ ni fún Olúwa. 31Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ra ìdámẹ́wàá nǹkan rẹ̀ padà: o gbọdọ̀ fi márùn-ún kún un. 32Gbogbo ìdámẹ́wàá àgbò àti ẹran ọ̀sìn, àní ìdámẹ́wàá ẹran tó bá kọjá lábẹ́ ọ̀pá darandaran kí ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa. 33Ènìyàn kò gbọdọ̀ wádìí bóyá ó dára tàbí kò dára, kò sì gbọdọ̀ pààrọ̀ rẹ̀. Bí ó bá pààrọ̀ rẹ̀: àti èyí tí ó pààrọ̀ àti èyí tí ó fi pààrọ̀ ni kí ó jẹ́ mímọ́. Wọn kò gbọdọ̀ rà á padà.’ ”

Copyright information for YorBMYO